Wikimedia Foundation Universal Code of Conduct

From Wikimedia Foundation Governance Wiki
This page is a translated version of the page Policy:Universal Code of Conduct and the translation is 93% complete.
Outdated translations are marked like this.
Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí

Ìdí tí afi ní Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí

Agbàgbó nínu ríró agbára fún gbogbo ènìyàn tí ó n kópa nínú àwọn iṣẹ́ àti àwọn àyè wikimedia, láti lè dé bi ìran wa fún dídá irú ayé tí gbogbo ènìyàn lè pín nínu àwọn àkópọ̀ ìmọ̀ àwa ọmọ aráyé. Agbàgbó wípé àwọn olùkópa àjọṣepọ̀ wa yìí gbọdọ̀ jẹ́ onírúurú ènìyàn, àjọṣepọ̀ yìí sì gbọdọ̀ fani mọ́'ra níwọ̀n bí óti ṣeése. Afẹ́ kí àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí máa wà ní dídára, pẹ̀lú ààbò t'ó pé'ye àti àyíká t'óní ìlera fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ wọn. A pinu láti ríi dájú pé ó wà báyìí, nípa fí'faramọ́ Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yìí àti ìmúdójúìwọ̀n ní gbà tí ó bá tọ́. Pẹ̀lúpẹ̀lú, afẹ́ dáàbò bo àwọn iṣẹ́ Wikimedia kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bàájẹ́ tàbí díilọ́wọ́.

Ní ìbámu pẹ̀lú àfojúsùn Wikimedia, gbogbo ẹni tí o bá ti ń kópa nínú iṣẹ́ Wikimedia yóò:

  • sapá láti ṣ'ẹ̀dá irú ayé tí gbogbo ènìyàn lè pín nínu àwọn àkópọ̀ ìmọ̀ àwa ọmọ aráyé
  • kopa nínú awujo àgbáyé tí yíò jìnà sí ẹ̀tanú àti ìkóríra, pẹ̀lú
  • sapá láti ríi dájú pé gbogbo àwọn iṣẹ́ Wikimedia pé dé ojú ìwọ̀n, ósì ṣeé jẹ́rìsí.

Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC) yìí ṣe àlàpín sí àwọn ìwà tí ó tọ̀nà àti àwọn ìwà tí kò bójú mu. Òfin yí de gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ní nkan ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àti àyeè àjọṣepọ̀ Wikimedia, yálà lórí ayélujára ni tabí ní ojúkojú. Òfin yí ta bá àwọn akópa titun tàbí àwọn tí wọ́n ti n kópa tipẹ́, àwọn alábòjútó àwọn iṣẹ́ Wikimedia, àwọn olùṣẹ̀tò àpẹ́jọ, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ onígbọ̀wọ́ àwọn ilé-iṣẹ́ Wikimedia, àwọn òṣìṣẹ́, àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation. Òfin yí ta bá àtèlé yìí:

  • ìbáṣepọ̀ àwùjọ ìkọ̀kọ̀, ti gbangba, tàbí èyí tí ó wà ní agbede méjì
  • àwọn ìjíròrò ti ìyapa àti àtìlẹ́yìn fún ìṣọ̀kan láàrin àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia
  • àwọn ọ̀rọ̀ lórí ìdàgbàsókè ìmọ̀-ẹ̀rọ̀ nà iṣẹ́
  • àwọn ọ̀rọ̀ tí ó dá lórí ṣíṣe àfikún àwọn àkòsílẹ̀
  • ìlànà bí àwọn ẹ̀ka aṣoju Wikimedia ṣe lè ṣojú wọn lọ́dọ̀ àwọn alábàáṣe wọn t'ìta

1 - Ìfihàn

Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ṣ'ètò ìpelẹ̀sẹ̀ iwà tí ó bójú mu fún àjọṣepọ̀ Wikimedia kárí àgbáyé. Àwọn ará Wikimedia ṣì le fikún àlàkalẹ̀ yìí láti ṣ'ẹ̀dá àlàkalẹ̀ tí yío j'ọmọ́ ṣakun àṣà, àti ìṣe tí ówà nílẹ̀, sùgbọ́n tí Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò sì gbodọ̀ jẹ́ ìpelẹ̀sẹ̀ fún.

Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yìí de gbogbo àwọn ará Wikimedia ní bá'kàan láì yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Tí'tàpá sí Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yìí lè mú ìjìyà dání. Àwọn ìjìyà yìí lè wá láti ọwọ́ àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe Wikimedia tàbí/àti láti ọwọ́ Wikimedia Foundation, gẹ́gẹ́ bí olóun àwọn iṣẹ́ àjọṣepọ̀ yìí

Template:Ìwàtí ó bójúMu

Gbogbo àwọn ará Wikimedia, yálà wọ́n ti pẹ́ ni tàbí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ sílẹ̀ ni, àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe Wikimedia, àwọn ẹ̀ka tàbí àwọn ìgbìmọ̀ onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation tàbí òṣìṣẹ́, ni won yóò ṣe ìdúró fún ìwà wọn.

Nínú gbogbo àwọn iṣẹ́, àyèè ati àpèjọ̀ Wikimedia, ìwà ìbọ̀wọ̀-fún, ìmẹ̀tọ́, ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn, ìṣọ̀kan àti ìjẹ́ aṣojú rere ni a ń retí lọ́wọ́ gbogbo àwọn olùkópa. Àwọn ìwà wọ̀nyí ni a gbọ́dọ̀ ma gbóòórùn lará àwọn oníṣẹ́ aláfikún àti olùkópa pátá nínú ìbáṣepọ̀ wọn láàríin ara wọn, láì yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ nípa ọjọ́-orí, ìpèníjà ara, ìṣesí, ìrísí, orílẹ̀-èdè, ẹ̀sìn, ẹlẹ́yà-mẹ̀yà, ìdẹ́yẹsíni, ipò-ayé, mímọ̀rọ̀'sọ, ìbálòpọ̀ akọ àti abo, ìjákọ tàbí ìjábo, ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ ayé. A ò sì ní yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ nípa ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ wọn nínú àjọṣepọ̀ Wikimedia.

<Ìbọ̀wọ̀ fún ara ẹni>

A ní láti máa bọ̀wọ̀ fún ara wa gẹ́gẹ́ bí a ṣe fẹ́ kí wọ́n o bọ̀wọ̀ fún àwa náà ní àwọn àyíká Wikimedia, yálà lórí ẹ̀rọ ayélujára ni tàbí ní ojúkojú. Agbọ́dọ̀ maa bọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn.x.

•Lará rẹ̀ tún ni:

  • |Síṣe ìgbatẹnirò. Fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí ẹnikẹ́ni nínú àwọn akẹgbẹ́ rẹ tí wọ́n jẹ́ onise Wikimedia ba fẹ́ sọ fún ọ. Gbaradì láti lo ìmọ̀ àti òyé rẹ lórí ohun tí o ti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Wikimedia.
  • <Jẹ́ kí ọkàn rẹ ó mọ́, kí o sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àròjinlẹ̀> Àfíkun rẹ gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe bá ìsẹ́ tí ò nfikún. Fèsì sí ọ̀rọ̀ pẹ́lú ẹ̀mí kan. Bí o bá ní ìyapa èrò lórí ọ̀rọ̀ kan, gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ pẹ̀lú àròjinlẹ̀. Gbogbo ará Wikimedia gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe pẹ̀lú ọkàn mímọ́, tí kòbá sí ẹ̀rí pé ẹnìkejì jẹ́ oníbàjẹ́. Pẹ̀lúpẹ̀lú, o kòsì gbọdọ̀ s'ọ̀rọ̀ ìpalára sí oníbàjẹ́ tí o bábá wọn pàdé.
  • Bọ̀wọ̀ fún bí àwọn oníṣẹ́ bá ṣe pe orúkọ tàbí ṣàpèjúwe ara wọn. Àwọn ènìyàn lè lo onírúurú ìlànà láti ṣàpèjúwe ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìbọ̀wọ̀ fún, lo ìlànà tí wọ́n bá fi pe ara won gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe lòó, nígbà tí o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ tàbí sọ̀rọ̀ nípa wọn, níwọ̀nbí ótiṣééṣe. Bí àpeere:
    • Àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀yà kan lè fi orúkọ pàtàkì láti ṣe àpèjúwè ara wọn, dípò orúkọ tí àwùjọ mọ̀ wọ́n sí.
    • Àwọn ènìyàn kan lè lo àwon lẹ́tà, ohùn, tàbí ọ̀rọ̀ láti inú èdè won tí yòò ṣàjòjì sí ìwọ;
    • Àwọn ènìyàn tí nṣe ìbálòpọ̀ akọ àti abo ọ̀tọ̀, léè lo arọ́pò orúkọ tó yàtọ̀;
    • Àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìpèníjà ara kan tàbí òmíràn lè lo ohunkóhun láti fi jùwé ara wọn.
  • Ní àwọn ìpàdé ojúkojú, a ó gbìyànjú láti fa gbogbo ènìyàn mọ́ra, a ó sì ri wípé a bu ọ̀wọ̀ fún àwọn àyòò, àlàà, ohun ìpalára, àṣà, àti ìbéèrè oníkálukú.

<<Ìwà-Ẹ̀tọ́, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ìṣọ̀kan àti ìjẹ́ asojú rere>>

Àwọnìwà tí à nretí nì yíí:

  • <<Ìwà-È̩tọ́>> ni mímọ ìwà, ọ̀rọ̀ àti ìṣesí tí ó tọ́ láàrin àwùjọ, pẹ̀lúpẹ̀lú àlejò.
  • Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ni ìkúnra-ẹni lápá tàbí àṣà ìranra-ẹni lọ́wọ́ tí ó yẹ láàrin àwọn alábàṣisẹ́pọ̀.
  • Ìṣọ̀kan àti ìjẹ́ aṣojú rere ni mímú ojúsẹ láti rí dájú wípé gbogbo àwọn isẹ́ Wikimedìà n so èso, wọ́n dùn ún ṣe, wọ́n sì n jẹ́ àwùjọ ààbò, àti fún ìdàgbàsókè àfojúsìn àjọṣepọ̀ Wikimedia.

Lará rẹ̀ náà tún ni:

  • Jẹ́ Atọ́nà àti Olùkọ́: Ran àwọn ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ lọ́wọ́ láti mọ̀nà àti láti ní ìmọ̀ kíkún lórí bí Wikimedia ṣe ń ṣiṣẹ́.
  • Fi ìṣòkan hàn. Máa ran àwọn oníṣẹ́ bíi tìrẹ lọ́wọ́ nígbà kúùgbà tí wọ́n bá nílò ìrànwọ́ rẹ, kí o sì sọ̀rọ̀-sókè fún wọn bí wọ́n bá n fi ẹ̀gbin kan wọ́n tí ó lòdì, gẹ́gẹ́ bí Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
  • Ṣè'fihàn, kí o sì dúpẹ́ fún iṣẹ́ tí àwọn olùfarajìn nṣe: Dúpẹ́ fún ìrànwọ́ àti isẹ́ wọn. Ṣè'rántí akitiyan wọn ní àwọn ibi tí ó ti yẹ.

3 - Ìwà tí kò bójú mu

Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yìí yóò ràn gbogbo àwọn ará wikimedia lọ́wọ́ láti lè ṣe àdáyanrí àwọn ipò ìwà tí kò tọ́. Àwọn ìwà wọ̀nyí ni a lè pè ní ìwà tí kò tọ́ láàrín àwùjọ àjọṣepọ̀ Wikimedia.

3.1 - Ìyọlẹ́nu

Èyí jẹ́ àwọn ìwà tí ó lè fa ìjayà tàbí ìbínú láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn. A lè wo ìwà kan gẹ́gẹ́ bí ìwà ìyọlẹ́nu nígbà tí ó bá ti kọjá ohun tí ènìyàn lè gbà mọ́ra ní àwùjọ àgbáyé ti onírúurú. Ìwà Ìyọlẹ́nu má n ṣábà wáyé ní pasè ẹ̀dùn ọkàn, pàápàá sí àwọn tí ó bá wà ní ìkoríta ìpalára, nípa kíkàn sí ibi-isẹ́, tàbí ọ̀rẹ́ àti ẹbí, láti fa ìdàmú tàbí ìdójútì. Ní ìgbà míràn, àwọn ìwà tí kò ní ewu ní ìsẹ̀lẹ̀ kan, lè padà di ìwà ìyọlẹ́nu, tí óbá wá nsẹlẹ̀ léra léra. Ara àwọn ìwà ìyọlẹ́nu ni:

  • È̩gbin tàbí Ìwọ̀sí: Ara èyí ni pípení lórúkọ kórúkọ, àbòsí, àti fífi èèbú ara búni. È̩gbin tàbí ìwọ̀sí ni bíbúni ní pasẹ̀ bí ẹni nà ṣe n ronú, bí o ṣe rí, ẹ̀yà àti ìran tí ó jẹ́, irúfẹ́ ẹ̀sìn tí ó n sìn, bí àṣà àti iṣẹ́ rẹ̀ ṣe rí, ìṣe ìbálòpọ̀ rẹ̀, yálà akọ ni tàbí abo, ọjọ́ orí rẹ̀ ni, ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ni tàbí àwọn nkan mííràn. Ní ìgbà mííràn, yí yẹ̀yẹ́ ẹni, ìfini rẹ́rìn tàbí ìfajúro síni léra léra sí ẹlòmíràn lè túmọ̀ sí ìwọ̀sí tàbí ẹ̀gbin l'ápàapọ̀, bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti lẹ̀ ṣe àìléwu.
  • Ìyọlẹ́nu ìbáṣepọ̀: Ìfàmọ́ra fún ìbáṣepọ̀ sí àwọn ènìyàn tí o mọ̀ pé wọ̀n fẹ́, tàbí sí àwọn ènìyàn tí ó yẹ kí o mọ̀ pé kò tọ̀ nà, tàbí ní àwọn ipò tí kò ṣéé ṣe làti bèèrè fún ìgbàláyè wọn.
  • Ìhàlẹ̀: Ìhàlẹ̀ ìwà-ipá mọ́ni ní ìpamọ́ tàbí ní gbangba, ìdójútì àìtọ́, ìbani lórúkọ jẹ́ àìtọ̀, tàbí dídábàá làti p'ènìyàn l'ẹ́jọ́ nítorí kí o lè borí iyàn tàbí fi t'ipá jẹ́ kí ènìyàn ṣe ohun tí o fẹ́.
  • Gbígbìmọ̀ ìkà fún àwọn ẹlòmíràn: Èyí lè jẹ́ nípa gbígba ẹlòmíràn ní ìyànjú láti ṣe ìpalára tàbí gbẹ̀mí ara rẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú gbígba ní'yànjú láti ṣe ìkà tàbí ìjàmbá fún ẹ̀lòmíràn.
  • Àṣírí títú: Ṣíṣe ìfihàn àwọn àṣírí ìkọ̀kọ̀ ẹni bíi: orúkọ, ibi-isẹ́, ibùgbé tàbí e-mail, lórí àjọsẹpọ̀ Wikimedia tàbí ibò míràn láì gba àṣe lọ́wọ́ oní tọ̀hún. Èyí tún jẹ́ ṣíṣe ìfihàn àwọn iṣẹ́ tí oníṣẹ́ nṣe lórí Wikimedia sí'ta.
  • Ṣíṣọ́'ni kiri: Títèlé ẹnikẹ́ni káàkiri gbogbo àwọn àjọṣe Wikimedia tí o sì n bu ẹnu àtẹ́ lu iṣẹ́ onítọ̀hún léraléra, pẹ̀lú èró ngbà láti mú wọn bínú, tàbí fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún wọn. Tí iṣẹ́ wọn bá n ní ìṣòro léraléra lẹ́yìn tí o ti gbìyànjú láti báwọn sọ̀rọ̀ àti kọ́ wọn, jẹ́ kí àwọn ará àjọṣepọ̀ t'ókù yanjú ọ̀rọ̀ oníṣẹ́ náà.
  • Ìtakoni kiri: Jíjáwọ àwọn ìjíròrò tí óníṣẹ́ wà káàkiri, lọ́nà tí kò tọ́ láti jẹ́ kí wọ́n bínú.

3.2 - ìlòkulò agbára, àǹfààní, tàbí òkìkí

Ìlòkulò má n wáyé nígbàtí ènìyàn tí ó wà ní ipò agbára, àǹfààní, tàbí òkìkí bá n hùwà àìbọ̀wọ̀, ìkà, àti/tàbí ipá sí àwọn ẹlòmíràn. Ní àwùjọ Wikimedia, ó lè wáyé ní ọ̀nà ìtakùrọ̀sọ tàbí mímú làákàyé ẹni ṣeré. A lè tún rí àwọn ìwà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìyọlẹ́nu.

  • Ìlòkulò ipọ̀ àwọn alábòjútó, olùdarí àti òṣìsẹ́: lílo ipọ̀ àṣe, ìmọ̀ tàbí àwọn ohun èlò tí ó wà ní àr'ọ́wọ́ tó àwọn alábòjútó, pẹ̀lú àwọn olùdarí àti òṣìsẹ́ Wikimedia Foundation tàbí ẹ̀ka Wikimedia, làti fi halẹ̀ tàbí ṣ'ẹ̀rùbà àwọn ẹlòmíràn.
  • Ṣíṣi ipò àjùlọ àti ìmọni lò: Lílo ipọ̀ tàbí orúkọ ẹni láti fi halẹ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn. À n re tí àwọn tí wọ́n ní ìrírí rẹpẹtẹ, tí wọ́n sì ti mọ àwọn ara àjọṣepọ̀ yìí káà kiri, wípé kí wọ́n hùwà pẹ̀lú ìsọ́ra, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ láti ẹnu wọn lè dá wàhálà nlá sílẹ̀. Àwọn ènìyàn pẹ̀lù àṣe ní ànfààní pàtàkì tí ó n mú kí àwọn ènìyàn di ọ̀rọ̀ wọn mú, wọn kò si gbọdọ̀ ṣi ànfààní yìí lò nípa jíjà pẹ̀lú àwọn tí ó bá ṣàìgba àwọn ìmọ̀ràn wọn.
  • Pípo làákàyè pọ̀: Gbígbìyànjú láti jẹ́ kí ènìyàn maa ṣe iyèméjì ohun tí wọ́n n rí, èrò wọn, tàbí òye wọn, nítorí kí o bà le jàre iyàn tàbí fi t'ipá jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí o fẹ́.

3.3 - Ìlòkulò tàbí ìbàjẹ́ àwọn iṣẹ́ Wikimedia

Mí mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn àfikún àbòsí, èké, irọ́ tàbí àìtọ̀nà, tàbí ṣíṣe ìdílọ́wọ́ ìṣèdá (àti/tàbí ìtọ́jú) àwọn àfikún míràn. Lára èyí ni:

  • Yíyọ àwọn àkòrí kùrò léraléra láì ṣe ìjíròrò tótọ́ tàbí ṣe àlàyé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
  • Yíyípo àwọn àkòrí ní sísèntèlé láti jẹ́ kí wọ́n ṣàtìlẹyìn fún àwọn ìtumọ̀ tí kò yẹ (pẹ̀lú mímọ̀ọ́mọ̀ yí àwọn ìtọ́kasí àti àfíkún kúrò ní ọ̀nà tí óti wà nlẹ̀)
  • Sís'ọ̀rọ̀ ìkóríra ní ọ̀nàkọnà, tàbí lílo èdè ẹlẹ́yàmẹ̀yà fún èébú, ìdójútìni, tàbí rírú ìkóríra sí ẹnìkan tàbí àwọn ẹgbẹ́ nítorí ìrí wọn tàbí ìgbàgbọ́ wọn
  • Lílo àwọn àmì, àwòrán, ẹ̀ka, ohun ìdánimọ̀ tàbí àwọn nkan míràn tí ó jẹ́ ohun ìjayà tàbí ìpalára sí àwọn ẹlòmíràn. Làra rẹ̀ ni dídarí àwọn ètò lórí àwọn àkórí tí ó n fa ìyapa.